Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 32:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí pé èmí kún fún ọ̀rọ̀ sísọ,èmí ń rọ̀ mi ni inú mi.

19. Kíyèsí i, ìkùn mi dàbí ọtí wáìnì,tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-àwọ̀ tuntun.

20. Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.

21. Lótítọ́ èmí kì yóò ṣe ojúṣàájú síẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.

22. Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ;ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.

Ka pipe ipin Jóòbù 32