Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 32:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Kíyèsí i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;Èmi fetísí àròyé yín, nígbà tíẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀nyín yóò sọ;

12. Àní mo fíyèsí yín tinútinú; sìkíyèsí i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jóòbù ní irọ́, tàbí tí ó lèdá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!

13. Kí ẹ̀yín kí ó má ṣe wí pé, àwa wáọgbọ́n ní àwárí: Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú, kì í ṣe ènìyàn.

14. Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi, bẹ́ẹ̀ni èmí kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.

15. “Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùnmọ́, wọ́n síwọ́ ọ̀rọ̀ ísọ́.

16. Mo si reti, nítorí wọn kò sìfọhún, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́; wọn kò sì dáhùn mọ́.

17. Bẹ́ẹ̀ ni èmí ò sì dáhùn nípa tièmí, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.

18. Nítorí pé èmí kún fún ọ̀rọ̀ sísọ,èmí ń rọ̀ mi ni inú mi.

19. Kíyèsí i, ìkùn mi dàbí ọtí wáìnì,tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-àwọ̀ tuntun.

20. Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.

21. Lótítọ́ èmí kì yóò ṣe ojúṣàájú síẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.

22. Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ;ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.

Ka pipe ipin Jóòbù 32