Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 31:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú niìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀àrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?

4. Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kòha sì ka gbogbo ìṣíṣẹ̀ mi?

5. “Bí ó bá ṣepé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn,tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn;

6. (Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ̀n mí nínú ìwọ̀nòdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)

7. Bí ẹṣẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tíàyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbíbí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀mọ́ mi ní ọwọ́,

8. Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmìírànkí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú ọmọ mi tu.

Ka pipe ipin Jóòbù 31