Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 30:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Èmi sáà mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọsínú ikú, sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.

24. “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóòha na ọwọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubu rẹ̀, tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.

25. Èmi kò ha sunkún bí fún ẹni tí ówà nínú ìṣòro? Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún talákà bí?

26. Nígbà tí mo fojú sọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé;nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.

27. Ikùn mí n ru kò sì sinmi; Ọjọ́ìpọ́njú ti dé bámi.

Ka pipe ipin Jóòbù 30