Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 30:15-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkànmi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.

16. “Àti nísinsin yìí ọkàn mí sì dà jádesíi; ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mí mú.

17. Òru gún mi nínú egungun mi, ìyítí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.

18. Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi, ó sì lẹ̀mọ́mi ní ara yíká bí ọrùn aṣọ ìlekè mi.

19. Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀,èmi sì dàbí eruku àti eérú.

20. “Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run ṣùgbọ́n,ìwọ kò dámi lóhùn; èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.

21. Ìwọ padà di ẹni ìkà sími; ọwọ́agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.

22. Ìwọ gbémi sókè sí inú ẹ̀fúùfù,ìwọ múmi fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátapáta.

23. Èmi sáà mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọsínú ikú, sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.

24. “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóòha na ọwọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubu rẹ̀, tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.

25. Èmi kò ha sunkún bí fún ẹni tí ówà nínú ìṣòro? Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún talákà bí?

26. Nígbà tí mo fojú sọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé;nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.

27. Ikùn mí n ru kò sì sinmi; Ọjọ́ìpọ́njú ti dé bámi.

28. Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́nkì í ṣe nínú òòrùn; èmi dìdedúró ní àwùjọ mo sì kígbé fún ìrànlọ́wọ́.

29. Èmi ti di arákùnrin ìkòokò, èmidi ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.

30. Àwọ̀ mi di dúdú ó sì ń bọ́wọ̀;egungun mi sì jórun fún oru.

31. Hapu orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀,àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sunkún.

Ka pipe ipin Jóòbù 30