Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 30:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnàsími, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sími lójú.

11. Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi,ó sì pọ́n mi lójú; àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìjánu níwájú mi.

12. Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apáọ̀tún mi; wọ́n tì ẹsẹ̀ mikúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dèmí.

13. Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sìsọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

14. Wọ́n ya sími bí i omi tí ó yagbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n kó ara wọn ká tì sí mi.

15. Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkànmi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 30