Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 30:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí,àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi míṣe ẹlẹ́yà, baba ẹni tí èmi kẹ́gànláti tò pẹ̀lú àwọn ajá agbo-ẹran mi.

2. Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sími,níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?

3. Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyànwọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹní ibi ìkọsílẹ̀ ní òru.

4. Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀báìgbẹ́; gbogbo igikígi ni ounjẹ jíjẹ wọn.

5. A lé wọn kúrò láàrin ènìyàn,àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.

Ka pipe ipin Jóòbù 30