Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 3:4-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn,kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá;bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.

5. Kí òkùnkùn àti òjìjì ikú fi ṣe ti ara wọn;kí àwọ-sánmọ̀ kí ó bà lé e;kí ìṣúdúdú ọjọ́ kí ó pa láyà.

6. Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri,kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà:kí ó má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.

7. Kí òru náà kí ó yàgàn;kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.

8. Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn-ún kí o fi gégùn-ún,tí wọ́n mura tán láti ru Léfíátánì sókè.

9. Kí ìràwọ̀ òféfé ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn;kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ síi,bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀rẹ̀mọ́jú mọ́

10. Nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi,bẹ́ẹ̀ ni kò pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.

11. “Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá,tàbí tí èmi kò fi pín ẹ̀mí ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?

12. Èéṣe tí eékún wá pàdé mi,tàbí ọmú tí èmi yóò mu?

13. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí èmi ìbá ti dúbúlẹ̀ jẹ́ẹ́;èmi a sì dákẹ́, èmi ìbá ti sùn ǹjẹ́ èmi ìbá ti sinmi

14. pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayétí ìmọ́lẹ̀ takété fún ara wọn.

15. Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládétí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn

16. Tàbí bí ọ̀lẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí:bí ọmọ ìṣúnú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?

17. Níbẹ̀ ni ẹni-búburú síwọ́ ìyọ nilẹ́nu,níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.

18. Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀,wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.

Ka pipe ipin Jóòbù 3