Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 3:16-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Tàbí bí ọ̀lẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí:bí ọmọ ìṣúnú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?

17. Níbẹ̀ ni ẹni-búburú síwọ́ ìyọ nilẹ́nu,níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.

18. Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀,wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.

19. Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀,ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.

20. “Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòsì,àti ìyè fún ọlọ́kan kíkorò,

21. tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá,tí wọ́n wálẹ̀ wá a jù fún ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́.

22. Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi,tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?

23. Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà rẹ̀fi ara pamọ́ fúntí Ọlọ́run sì ṣọgbà yí wọn ká?

24. Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi;ikérora mi sì tú jáde bí omi.

25. Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí,àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.

Ka pipe ipin Jóòbù 3