Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yìn èyí ní Jóòbù yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré

2. Jóòbù sọ, ó sì wí pé:

3. “Kí ọjọ́ tí a bi mi kí ó di ìgbàgbé,àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A loyún ọmọkùnrin kan!’

4. Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn,kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá;bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.

5. Kí òkùnkùn àti òjìjì ikú fi ṣe ti ara wọn;kí àwọ-sánmọ̀ kí ó bà lé e;kí ìṣúdúdú ọjọ́ kí ó pa láyà.

6. Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri,kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà:kí ó má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.

7. Kí òru náà kí ó yàgàn;kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.

8. Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn-ún kí o fi gégùn-ún,tí wọ́n mura tán láti ru Léfíátánì sókè.

9. Kí ìràwọ̀ òféfé ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn;kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ síi,bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀rẹ̀mọ́jú mọ́

10. Nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi,bẹ́ẹ̀ ni kò pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.

Ka pipe ipin Jóòbù 3