Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 29:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí,àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já;

4. Bí mo tirí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbàtí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi

5. Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi,nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;

6. Nígbà tí èmi fi òrí àmọ́ n wẹ ìsísẹ̀ mi,àti tí àpata ń tú ìsàn òróró jáde fún mi wá.

7. “Nígbà tí mo jáde la àárin ìlú lọ síẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,

8. Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rími, wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹṣẹ̀ wọn;

9. Àwọn ọmọ aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sí sọ,wọn a sì fí ọwọ́ wọn lé ẹnu;

Ka pipe ipin Jóòbù 29