Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 29:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹṣẹ̀fún amúkùnún.

16. Mo ṣe baba fún talákà, mo ṣeìwádìí ọ̀ràn àjòjì tí èmi kò mọ̀ rí.

17. Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìkà ènìyàn,mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.

18. “Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóòkú nínú ilé mi, èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí i yanrìn.

19. Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi, ìrìyóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.

20. Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀mi, ọrun mi sì padà di titun ní ọwọ́ mi’

21. “Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí, wọna sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.

Ka pipe ipin Jóòbù 29