Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 24:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò níẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ talákà. Nítorí gbèsè

10. Wọ́n rìn kiri níhòòhò láìní aṣọ;àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà,

11. Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínúàgbàlá wọn, tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntíàjàrà, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn.

12. Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́kígbe sókè; fún ìrànlọ́wọ́ ṣíbẹ̀Ọlọ́run kò kíyèsí àṣìṣe náà.

13. “Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó kọ̀ìmọ́lẹ̀; Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.

14. Panipani a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́,a sì pa talákà àti aláìní, àti ní òru a di olè.

Ka pipe ipin Jóòbù 24