Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 23:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta niyóò sì yí i padà? Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.

14. Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi níí ṣe; ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.

15. Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ míníwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.

16. Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,Olodùmáarè sì ń dààmú mi,

17. Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúròníwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò paòkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.

Ka pipe ipin Jóòbù 23