12. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrònínú òfin ẹ̀nu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ
13. “Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta niyóò sì yí i padà? Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.
14. Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi níí ṣe; ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.
15. Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ míníwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
16. Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,Olodùmáarè sì ń dààmú mi,
17. Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúròníwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò paòkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.