Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 23:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ni Jóòbù sì dáhùn wí pé:

2. “Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò; ọwọ́mí sì wúwo sí ìkérora mi.

3. Áà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wáỌlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!

4. Èmi ibá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.

5. Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dámi lóhùn; òye ohun tí ìbá wí a sì yé mi.

6. Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsí mi.

Ka pipe ipin Jóòbù 23