Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 20:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí ijáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.

16. Ó ti fà oró pamọ́lẹ̀ múu; ahọ́ngúnte ní yóò pa á.

17. Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi,odò tí ń sàn fún oyin àti ti òrí àmọ́.

18. Ohun tí ó ṣíṣẹ́ fún ni yóò mú unpadà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì yọ̀ nínú rẹ̀.

19. Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni talákà lára,ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n;Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.

20. “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínúara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkán rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.

21. Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀;Nitorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.

22. Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a;àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́ jọ lé e lórí.

Ka pipe ipin Jóòbù 20