Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 20:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ní Sófárì, ara Náámà dáhùn, ó sì wí pé:

2. “Nítorí náà ní ìro inú mi dá mi lóhùn,àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.

3. Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òyemi sì dá mi lóhùn.

4. “Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́,láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ silẹ̀ ayé,

5. Pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbàkúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?

6. Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, tiori rẹ̀ sì kan àwọsánmà;

7. Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’

8. Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i,àní a ó lé e lọ bi ìran òru.

9. Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.

Ka pipe ipin Jóòbù 20