Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 19:20-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ẹran ara mi, mo sì bọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.

21. “Ẹ ṣáànú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.

22. Nitorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bíỌlọ́run, tí ẹran ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?

23. “Áà! Ìbáṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ minísinsìn yìí, ìbáṣepé a le dà á sínú ìwé!

24. Kí a fi kálàmú irin àti ti òjé kọwọ́n sínú àpáta fún láéláé.

25. Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáùndè miń bẹ láàyè àti pe òun ni yóò dìdedúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;

26. Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ arami run, síbẹ̀ láìsí ẹran ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,

27. Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi, tí ojúmi ó sì wo, kì sì íṣe tiẹlòmìíràn; ọkàn mi sì dákú ní inú mi.

28. “Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘àwa ó ti lépa rẹ̀ tó!Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a ṣáà rí ní ọwọ́ rẹ̀,’

29. Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù; nítorí ìbínú níímú ìjìyà wá nípa ìdàKí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”

Ka pipe ipin Jóòbù 19