Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 19:2-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyàjẹ mí, tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ mi ní ìjàǹjá?

3. Ìgbà mẹ́wàá ní ẹ̀yin ti ń gàn mí;ojú kò tìyín tí ẹ fi jẹ mí níyà.

4. Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo sìnà nítòótọ́,ìsìnà mi wà lára èmi tìkáarami.

5. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si milórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,

6. Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni óbì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

7. “Kiyè sì í, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára;’ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdajọ́.

8. Ó sọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le èkọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.

9. Ó ti bọ́ ògo mi,ó sì sí adé kúrò ní orí mi.

10. Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.

11. Ó sì tinábọ ìbínú rẹ̀ sími,ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.

12. Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́nsì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yíàgọ́ mi ká.

13. “Ó mú àwọn arákùnrin mi jìn nàsí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ midi àjèjì sí mi pátapáta.

Ka pipe ipin Jóòbù 19