Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 19:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ni Jóòbù dáhùn, ó sì wí pé:

2. “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyàjẹ mí, tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ mi ní ìjàǹjá?

3. Ìgbà mẹ́wàá ní ẹ̀yin ti ń gàn mí;ojú kò tìyín tí ẹ fi jẹ mí níyà.

4. Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo sìnà nítòótọ́,ìsìnà mi wà lára èmi tìkáarami.

5. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si milórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,

6. Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni óbì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

7. “Kiyè sì í, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára;’ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdajọ́.

8. Ó sọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le èkọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.

9. Ó ti bọ́ ògo mi,ó sì sí adé kúrò ní orí mi.

10. Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.

Ka pipe ipin Jóòbù 19