5. “Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni aó pa kúrò, Ọ̀wọ́ iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.
6. Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́rẹ̀, fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.
7. Ìrìn ẹṣẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọn;ìmọ́lẹ̀ òun tìkárarẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.
8. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkararẹ̀ ó ti bọ́ sínúàwọ̀n, ó sì rìn lóri okùn dídẹ.
9. Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀,àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.
10. A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sìwà ọ̀fìn fún un lojú ọ̀nà.