Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 18:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. A ó sì lée láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inúòkùnkùn, a ó sì lé e kúrò ní ayé.

19. Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọnínu àwọn ènìyàn rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni kòsí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.

20. Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà oòrùn.

21. Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọnènìyàn búburú Èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run.”

Ka pipe ipin Jóòbù 18