Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 16:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín niìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.

6. “Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò tù;bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí dé?

7. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá milágara; Ìwọ (Ọlọ́run) mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.

8. Ìwọ sì fi ìkiyẹ̀jẹ kùn mí lára, tí ójẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó yọ lára mi, ó jẹ́rìí lòdì sí ojú mi.

9. Ọlọ́run fi Ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ósì ṣọ̀tá mi; ó pa eyín rẹ̀ keke sími, ọ̀ta mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.

10. Wọ́n ti fi ẹnu wọn yán sí mi;Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbáẹ̀gàn; Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.

11. Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹnibúburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.

12. Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;ó sì dì mí ọrùn mú, ó sì gbọ̀nmí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ ṣe àmì—ìtàfàsí rẹ̀.

13. Àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mikákiri; ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò sidásí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.

14. Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;ó súré kọlù mi bí jagunjagun.

15. “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ n bò ara mi, mosì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

16. Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikúsì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.

17. Kì í ṣe nítorí àìsòótọ́ kan ní ọwọ́mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.

18. “Áà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.

Ka pipe ipin Jóòbù 16