2. “Èmi ti gbọ́ irú ohun pípọ̀ bẹ́ẹ̀ ríayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.
3. Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin? Tàbí nín ni ógbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?
4. Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin; bí ọkànyín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmile íkọ ọ̀rọ̀ pọ̀ si yin ni ọ̀run, èmi a sì mi orí mi sí i yín.
5. Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín niìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.
6. “Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò tù;bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí dé?
7. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá milágara; Ìwọ (Ọlọ́run) mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.
8. Ìwọ sì fi ìkiyẹ̀jẹ kùn mí lára, tí ójẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó yọ lára mi, ó jẹ́rìí lòdì sí ojú mi.
9. Ọlọ́run fi Ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ósì ṣọ̀tá mi; ó pa eyín rẹ̀ keke sími, ọ̀ta mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
10. Wọ́n ti fi ẹnu wọn yán sí mi;Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbáẹ̀gàn; Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.
11. Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹnibúburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.