Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 16:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;ó súré kọlù mi bí jagunjagun.

15. “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ n bò ara mi, mosì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

16. Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikúsì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.

17. Kì í ṣe nítorí àìsòótọ́ kan ní ọwọ́mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.

18. “Áà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.

19. Ǹjẹ́ nísinsinyí kíyèsí i, ẹlẹ́rìí miń bẹ ní ọ̀run, ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.

20. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run;

21. Ìbáṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwífún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,bí ènìyàn kan ti íṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.

22. “Nítorí nígbà tí iye ọdun díẹ̀ rékọjátán, nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 16