Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 15:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “Ìwọ ha íse ọkùnrin tí a kọ́ bi? Tabìa há dá ọ ṣáájú àwọn òkè?

8. Ìwọ gburòó àsírí Ọlọ́run rí, tàbíìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?

9. Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀? Òyekí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?

10. Eléwú ogbó àti ògbólógbòóènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n gbójú baba rẹ lọ.

11. Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?

12. Èéṣe ti àyà rẹ fi ń dà ọ kiri,kí ni n mú ojú rẹ se wàìwàì.

13. Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì síỌlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?

14. “Kí ni ènìyàn tí ó fi mọ́? Àti ẹni tía tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?

Ka pipe ipin Jóòbù 15