Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 15:30-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Òun kì yóò jáde kúrò nínúòkùnkùn; ọ̀wọ́ iná ni yóò jóẹ̀ka rẹ̀, àti nípaṣẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ní yóò máa kọjá lọ kúrò.

31. Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀le asán,kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.

32. A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípẹ́ ọjọ́ rẹ̀,ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.

33. Yóò sì gbọ̀n àìpọ́n èṣo rẹ̀ dànù bí i àjàrà,yóò sì rẹ̀ ìyanna rẹ̀ nù bí i ti igi Ólífì.

34. Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebèyóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

35. Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bíẹ̀ṣẹ̀, ikùn wọn sì pèṣè ẹ̀tàn.”

Ka pipe ipin Jóòbù 15