Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 15:18-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn latiọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,

19. Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.

20. Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lúìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iyeọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.

21. Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.

22. O kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrònínú òkùnkùn; a sì ṣà á sápákan fún idà.

23. Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé,níbo ní ó wà? Ó mọ̀ pé ọjọ́òkùnkùn súnmọ́ tòsí.

24. Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú unbẹ̀rù, wọ́n ó sì sẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ímúra ogun.

25. Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdìsí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmáarè,

26. Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn giga, àní fiìké kòóko àpáta rẹ̀ tí ó nipọn kọlù ú.

27. “Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀lojú, o sì ṣe jabajaba ọ̀rá sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

28. Òun sì gbé inú ahoro ìlú ìtakété,àti nínú iléyílé tí ènìyàn kò gbémọ́, tí ó múra tán lati di àlàpà.

29. Òun kò lé ìlà, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kòlè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

30. Òun kì yóò jáde kúrò nínúòkùnkùn; ọ̀wọ́ iná ni yóò jóẹ̀ka rẹ̀, àti nípaṣẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ní yóò máa kọjá lọ kúrò.

Ka pipe ipin Jóòbù 15