Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 15:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Eléwú ogbó àti ògbólógbòóènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n gbójú baba rẹ lọ.

11. Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?

12. Èéṣe ti àyà rẹ fi ń dà ọ kiri,kí ni n mú ojú rẹ se wàìwàì.

13. Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì síỌlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?

14. “Kí ni ènìyàn tí ó fi mọ́? Àti ẹni tía tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?

15. Kíyèsí i, òun (Ọlọ́run) kògbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀;

16. Ańbọ̀tórí ènìyàn, ẹni ìríra àtieléèérìí, tí ń mù ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mú omi.

17. “Èmi ó fihàn ọ́: gbọ́ ti èmi; Èyí tíèmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,

18. tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn latiọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,

19. Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.

20. Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lúìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iyeọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.

21. Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.

Ka pipe ipin Jóòbù 15