Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 15:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ní Élífásì, ará Témà, dáhùn wí pé:

2. “Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kíó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà oòrun kún ara rẹ̀ nínú?

3. Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò níèrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?

4. Ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí àdúràlọ́nà níwájú Ọlọ́run.

5. Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.

6. Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi;àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí tì ọ́.

Ka pipe ipin Jóòbù 15