Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 14:8-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;

9. Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi,yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.

10. Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;Àní ènìyàn jọwọ́ ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́: Òun ha dà?

11. “Bí omi tí i sàn nínú ipa odò,tí odò sì ífà tí sì ígbẹ,

12. bẹ́ẹ̀ ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.

13. “Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!

14. Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.

15. Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ ń káye ìsísẹ̀ mi;ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?

17. A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,ìwọ sì rán àìṣedédé mi pọ̀.

18. “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ódasán, a sì sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.

19. Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sìmú omi ṣàn bo ohun tí ó hù jáde lóri ilẹ̀,ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.

20. Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjálọ; Ìwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.

21. Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òunkò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀,òun kò sì kíyèsìí lára wọn.

Ka pipe ipin Jóòbù 14