Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 14:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lèsinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.

7. “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a báké e lulẹ̀, pé yóò sì tún ṣọ, àtipé ẹ̀ka rẹ̀ titun kì yóò dá.

8. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;

9. Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi,yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.

10. Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;Àní ènìyàn jọwọ́ ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́: Òun ha dà?

Ka pipe ipin Jóòbù 14