Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 14:3-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni?Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?

4. Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ látiinú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!

5. Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, ìye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;Ìwọ ti pàlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.

6. Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lèsinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.

7. “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a báké e lulẹ̀, pé yóò sì tún ṣọ, àtipé ẹ̀ka rẹ̀ titun kì yóò dá.

8. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;

9. Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi,yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.

10. Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;Àní ènìyàn jọwọ́ ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́: Òun ha dà?

11. “Bí omi tí i sàn nínú ipa odò,tí odò sì ífà tí sì ígbẹ,

12. bẹ́ẹ̀ ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.

13. “Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!

14. Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.

15. Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ ń káye ìsísẹ̀ mi;ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?

17. A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,ìwọ sì rán àìṣedédé mi pọ̀.

18. “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ódasán, a sì sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 14