Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 14:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “Bí omi tí i sàn nínú ipa odò,tí odò sì ífà tí sì ígbẹ,

12. bẹ́ẹ̀ ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.

13. “Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!

14. Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.

15. Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ ń káye ìsísẹ̀ mi;ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?

17. A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,ìwọ sì rán àìṣedédé mi pọ̀.

18. “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ódasán, a sì sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.

19. Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sìmú omi ṣàn bo ohun tí ó hù jáde lóri ilẹ̀,ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.

20. Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjálọ; Ìwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.

21. Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òunkò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀,òun kò sì kíyèsìí lára wọn.

22. Ṣùgbọ́n ẹran ara rẹ̀ ni yóò ríìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”

Ka pipe ipin Jóòbù 14