Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 14:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ènìyàn tí a bí nínú obìnrinọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.

2. Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sìké e lulẹ̀; Ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.

3. Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni?Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?

4. Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ látiinú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!

5. Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, ìye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;Ìwọ ti pàlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.

6. Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lèsinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.

7. “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a báké e lulẹ̀, pé yóò sì tún ṣọ, àtipé ẹ̀ka rẹ̀ titun kì yóò dá.

8. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;

9. Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi,yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.

10. Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;Àní ènìyàn jọwọ́ ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́: Òun ha dà?

Ka pipe ipin Jóòbù 14