Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 13:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ó ha dára tí yóò fi húdìí yín sílẹ̀,Tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti ítan ẹnìkejì?

10. Yóò máa bá yín wí nítòótọ́, Bíẹ̀yin bá ṣojúusájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.

11. Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí?Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?

12. Ìrántí yín dàbí eérú;Ìlú odi yín ìlú odi amọ̀.

13. “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi,kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ohun tí ńbọ̀ wá íbá mi, kí ó máa bọ̀.

14. Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi èyín mibu ẹran ara mi jẹ, Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?

15. Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e;Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.

16. Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi,Àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.

17. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfàyàbalẹ̀, àti àṣọpé mí ni etí yín.

18. Wò ó nísinsin yìí, èmi ti làdí ọ̀ran mi sílẹ̀;èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.

Ka pipe ipin Jóòbù 13