Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 13:24-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́,tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?

25. Ìwọ ó fa ewé ya ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún?Ìwọ a sì máa lépa àkémọ́lẹ̀ pòròpórò gbígbẹ?

26. Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi,o sì mú mi ní àìṣedéédéé èwe mi.

27. Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú,ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín;Ìwọ sì ń fi ìlà yí gìgisẹ̀ mi ká.

28. “Àní, yí ẹni tí á ti run ká, bí ohuntí ó bu, Bí aṣọ tí kòkòrò jẹ bàjẹ́.

Ka pipe ipin Jóòbù 13