Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 13:2-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú,èmi kò rẹ̀yìn sí yin.

3. Nítòótọ́ èmi ó bá Olódumárèsọ̀rọ̀, Èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.

4. Èyin ni oníhùmọ̀ èké, oníṣègùnlásán ni gbogbo yín

5. Áà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyi nikì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.

6. Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsìn yìí, Ẹ sìfetísilẹ̀ sí àròyé ètè mi.

7. Èyin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run? Kiẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?

8. Ẹ̀yin fẹ́ ṣojúṣaajú rẹ̀? Ẹ̀yin fẹ́gbèjà fún Ọlọ́run?

9. Ó ha dára tí yóò fi húdìí yín sílẹ̀,Tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti ítan ẹnìkejì?

10. Yóò máa bá yín wí nítòótọ́, Bíẹ̀yin bá ṣojúusájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.

11. Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí?Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?

12. Ìrántí yín dàbí eérú;Ìlú odi yín ìlú odi amọ̀.

13. “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi,kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ohun tí ńbọ̀ wá íbá mi, kí ó máa bọ̀.

14. Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi èyín mibu ẹran ara mi jẹ, Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?

15. Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e;Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 13