Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 13:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí,Etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé e.

2. Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú,èmi kò rẹ̀yìn sí yin.

3. Nítòótọ́ èmi ó bá Olódumárèsọ̀rọ̀, Èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.

4. Èyin ni oníhùmọ̀ èké, oníṣègùnlásán ni gbogbo yín

5. Áà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyi nikì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.

6. Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsìn yìí, Ẹ sìfetísilẹ̀ sí àròyé ètè mi.

7. Èyin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run? Kiẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?

Ka pipe ipin Jóòbù 13