Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 12:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòòhò,A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18. Ó tú ìdè ọba,Ó sì fi mú àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.

19. Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòòhò,Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.

20. Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò,Ó sì ra àwọn àgbààgbà ní iyè.

21. Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́là,Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.

22. Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá,Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 12