Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 12:12-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún,Àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye?

13. “Pẹ̀lú rẹ Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára:Òun ni ìmọ̀ àti òye.

14. Kíyèsí i, ó bì wó, a kò sì lè gberó mọ́;Ó ṣé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìsísílẹ̀ kan.

15. Kíyèsí i, ó dá àwọn omi dúró,wọ́n sì gbẹ; Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì sẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.

16. Pẹ̀lú rẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun;Ẹni tí ń sìnà àti ẹni tí ń mú ni sìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.

17. Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòòhò,A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18. Ó tú ìdè ọba,Ó sì fi mú àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.

19. Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòòhò,Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.

Ka pipe ipin Jóòbù 12