Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 12:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jóòbù sì dáhùn, ó sì wí pé:

2. “Kò sí àní-àní níbẹ̀,ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!

3. Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin:èmi kò rẹ̀yìn sí i yín:àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?

4. “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn:à ń fi olóòótọ́ ẹni-ìdúró-ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

Ka pipe ipin Jóòbù 12