Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 11:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ni Sófárì, ará Naamáa, dáhùn, ó sì wí pé:

2. “A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀?A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?

3. Ṣé àmọ̀tàn rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí?Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?

4. Ìwọ sáà ti wí fún Ọlọ́run pé,‘ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní óju rẹ.’

5. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀,kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ lára;

6. Kí ó sì fi àsírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ;Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run tigbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.

7. “Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí?Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olodùmáarè dé bi?

8. Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe?Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?

9. Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,ó sì ní ibú ju òkun lọ.

10. “Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sénà,tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdajọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?

11. Òun sáà mọ ènìyàn asán;àti pé ṣé bí òun bá rí ohunbúburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?

12. Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn yóò di ọlọgbọ́n,nígbà tí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ènìyàn.

13. “Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un,tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,

Ka pipe ipin Jóòbù 11