Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 11:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ni Sófárì, ará Naamáa, dáhùn, ó sì wí pé:

2. “A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀?A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?

3. Ṣé àmọ̀tàn rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí?Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?

4. Ìwọ sáà ti wí fún Ọlọ́run pé,‘ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní óju rẹ.’

5. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀,kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ lára;

6. Kí ó sì fi àsírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ;Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run tigbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.

7. “Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí?Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olodùmáarè dé bi?

8. Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe?Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?

9. Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,ó sì ní ibú ju òkun lọ.

10. “Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sénà,tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdajọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?

11. Òun sáà mọ ènìyàn asán;àti pé ṣé bí òun bá rí ohunbúburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?

Ka pipe ipin Jóòbù 11