Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 10:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Tí ìwọ fi ń bèèrè àìṣedédé mi,tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?

7. Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú,kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?

8. “Ọwọ́ rẹ ni ó dámi,tí ó sì mọ mí pọ̀ yíkákiri;síbẹ̀ ìwọ sì ńbà mí jẹ́.

9. Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ tí ìwọ timọ mí bí amọ̀; ìwọ yóò ha sìtún mú mi lọ padà sí erùpẹ̀?

10. Ìwọ kò ha ti tún mí dà jáde bí i wàrà,ìwọ kò sì múmí dípò bí i wàràǹkàsì?

11. Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran ara wọ̀ mí,ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.

12. Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojú rere,ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.

Ka pipe ipin Jóòbù 10