Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jónà 3:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Nínéfè, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú.

7. Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Nínéfè pé:“Kí a la Nínéfè já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbààgbà rẹ̀ pé:“Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́-ẹran tàbí agbo-ẹran, tọ́ ohunkóhun wò: má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi.

8. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn.

9. Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?”

10. Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn: Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.

Ka pipe ipin Jónà 3