Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jónà 3:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jónà wá nigbà kejì wí pé:

2. “Dìde lọ sí Nínéfè, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.”

3. Jónà sì dìde ó lọ sí Nínéfè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Nínéfè jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta.

4. Jónà sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ̀n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Nínéfè wó.”

5. Àwọn ènìyàn Nínéfè sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ lati orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.

6. Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Nínéfè, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú.

Ka pipe ipin Jónà 3