Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jónà 2:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà náà ni mo wí pé,‘a ta mí nù kúrò níwájú rẹ;ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ èmi yóò túnmáa wo ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ.’

5. Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn;ibú yí mi káàkiri,a fi koríko odò wé mi lórí.

6. Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ àwọn òkè ńlá;ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí:ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, Olúwa Ọlọ́run mi.

7. “Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi,èmi rántí rẹ, Olúwa,àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ.

8. “Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èkékọ àánú ara wọn sílẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rúbọ sí ọ.Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́.‘Igbàlà wá láti ọdọ Olúwa.’ ”

10. Olúwa sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jónà sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.

Ka pipe ipin Jónà 2