Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jónà 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jónà ọmọ Ámítaì wá, wí pé:

2. “Dìde lọ sí ìlú ńlá Nínéfè kí o sì wàásù sí i, nítorí ìwà búburú rẹ̀ gòkè wá iwájú mi.”

3. Ṣùgbọ́n Jónà dìde kúrò láti sá lọ sí Tásísì kúrò níwájú Olúwa, ó sì ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí Jópà, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tásísì: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tásísì kúrò níwájú Olúwa.

4. Nígbà náà ni Olúwa rán ìjì ńlá jáde sí ojú òkun, ìjì líle sì wà nínú òkun tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́.

5. Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́.Ṣùgbọ́n Jónà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra.

Ka pipe ipin Jónà 1